Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Pàṣẹ Láti Gbé Ẹ̀ka Àwọn Ọmọ-ogún Kán Lọ Sí Ìpínlẹ̀ Kwara ‎

99

Ààrẹ Bola Tinubu ti pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ẹ̀ka àwọn ọmọ-ogun kan lọ sí ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama ní Ìpínlẹ̀ Kwara lẹ́yìn ìkọlù alẹ́ kan láti ọwọ́ àwọn oníjàgídíjàgan Boko Haram tó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí àwọn aráàlú ní agbègbè Worro.

‎ Àṣẹ náà, tó ní yíyàn olórí tuntun nínú àti pápá ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ológun. Ààrẹ sọ èyí nínú ọrọ kan ti Agbẹnusọ Ààrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga gbé jáde.

‎Gẹ́gẹ́ bí ọrọ náà ti sọ, Ààrẹ sọ pé àjọ ológun tuntun tí a gbé kalẹ̀ tí a pe ní ‘Operation Savannah Shield’ yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti kojú ìgbòkègbodò àwọn oníjàgídíjàgan àti láti dáàbò bo àwọn agbègbè náà.

‎Ààrẹ Tinubu tún pàṣẹ pé kí wọ́n rí i dájú pé àwọn olùgbé àgbègbè tí wọ́n kọlù náà rí ìtura lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí ó sì mú ààbò padà sí agbègbè náà.

‎Ní dídá ìkọlù náà lẹ́bi, Ààrẹ ṣàpèjúwe àwọn olùkọlù náà gẹ́gẹ́ bí aláìláàánú ọdaràn, fún kikọlu àwọn aráàlú tí kò ní òun ìjà lọwọ.

Comments are closed.

button