Take a fresh look at your lifestyle.

Ile-iṣẹ Ojú Afẹ́fẹ́ Nàìjíríà Tún Fí Ìpinnu Rẹ̀ Hàn Láti Dáàbò Bó Àwọn Aráàlú

75

Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogún ojú Afẹ́fẹ́ ti Nàìjíríà (NAF) tí tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ààbò àwọn aráàlú lo jẹ́ wọn logun l’ẹnu iṣẹ́ wọn.

‎ Èyí wa lẹyìn tí ikọ àwọn ọmọ ogún náà gbá ìròyìn tó sọ pé àwọn aráàlú ku nínú ìkọlù inú afẹ́fẹ́ tí wọ́n ṣe sí àwọn oníjàgídíjàgan ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ kàrún ún dín l’ọgbọn (25) Oṣù Kíní ọdún 2026, ní abúlé Kurigi, Àgbègbè Kontokoro ti Ìjọba ìbílẹ̀ Mariga, Ìpínlẹ̀ Niger,

‎Nínú àlàyé kan, Olùdarí Ibaraẹnisọrọ ati Alaye tí ile-iṣẹ ogun náà, Air Commodore Ehimen Ejodame ṣàlàyé pé ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ wọn, NAF ti mú ẹgbẹ́ aṣewadii Ìjàmbá àti Ìpalára Aráàlú (CHAI) láti ṣiṣẹ́ ìwádìí lẹsẹkẹsẹ pàápàá jùlọ, lórí iṣẹlẹ tí wọ́n ròyìn náà.

Comments are closed.

button