Take a fresh look at your lifestyle.

Ọdún Àjínde: Makinde Pé Fún Ádùrá Bó Ṣe Yayọ Pẹ̀lú Àwọn Kristẹni

8

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti yayọ ọdún Àjínde pẹ̀lú Kristẹni ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti jákèjádò Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde ti Amugbalẹgbẹ fún Gómìnà lórí ìròyìn Ọ̀mọ̀wé Suleimon Olanrewaju fi síta ṣe ṣàlàyé pé Gómìnà gba gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà níyànjú láti lò àsìkò ọdún yìí, eléyìí to ṣàmì ikú àti àjínde Jésù kristi Olúwa láti gbàdúrà fún orilẹ èdè yìí àti àwọn adarí rẹ̀.

Bákan náà ní Gómìnà Makinde ké sí gbogbo Kristẹni láti kọ́ ẹ̀kọ́ tó wà nínú ikú Kristi lórí agbelebu àti àjínde rẹ̀.

O wá gbàdúrà kí ìbùkún Ọlọrun wà pẹlú gbogbo ọkàn kọọkan ní àsìkò yìí ati láéláé.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button