Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò Ẹkùn Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP: Makinde Gbé Òṣùbà Káre Fún Àṣeyọrí Ìpàdé Ìdìbò Yan Aláṣẹ Ẹkùn.

7

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti gbé òṣùbà káre fún ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party, PDP fún ọ̀nà ti ẹgbẹ́ náà gbà láti dibò yan àwọn Aláṣẹ Ẹkùn ti yóò tukọ̀ ẹgbẹ́ náà fún ọdún mẹrin míràn.

Makinde, ẹni tó tẹnu mọ́ọ pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti fi àpẹẹrẹ bí ìpàdé gbogboògbò ẹgbẹ́ náà yóò ti rí ní ọjọ́ iwájú, nígbà tó ṣàlàyé pé ìpàdé tó wáyé láti yan àwọn aláṣẹ ẹkùn náà ti fihàn pé Ẹkun Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn yóò tubọ̀ máa ṣe àpẹẹrẹ bí òṣèlú àwa-ara-wa yẹ kó ṣe rí.

Gómìnà ló sọ ọ̀rọ̀ yii ní gbàngàn Theophilus Ogunlesi, tó wà ní UCH, ní Ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà nibi ti àwọn aṣojú ẹgbẹ náà ti péjú lati Yan àwọn aláṣẹ ẹkùn.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Aṣòfin Ademola Adélékè kín ọ̀rọ̀ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde lẹ́yìn nígbà ti òun náà gbé òṣùbà káre fún àwọn aṣojú fún àṣeyọrí ìdìbò yan àwọn aláṣẹ ẹkùn ẹgbẹ́ náà.

Adeleke wa fi àsìkò náà ké sí àwọn ẹkùn yòókù láti wo àwòkọ́ṣe lára Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn nítorí gbogbo wọn ló fi ohùn ṣọ̀kan nígbà tó tẹnu mọ́ pé kò sí dàrú-dàpọ̀ nínú yíyan gbogbo àwọn aláṣẹ ti wọn dìbò yàn.

Nígbà tí àwọn aṣojú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀ṣun, Òndó, Èkìtì, Ògùn, àti Ìpínlẹ̀ Èkó fi ohùn ṣọ̀kan láti yan àwọn wọnyii lẹ́ẹ̀kan si:
Alahji Kamorudeen Ajisafẹ gẹ́gẹ́ bíi igbákejì Alága gbogboògbò (Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn); Obagunwa Muyiwa, gẹ́gẹ́ bíi Akọwe Ẹkùn; Alhaja Bosede Adedibu, gẹ́gẹ́ bii Olori àwọn Obìnrin Ẹkùn.

Bákan náà ni àwọn aṣojú náà dìbò yan lẹ́ẹ̀kan síi Adeyemo Adetunji gẹ́gẹ́ bíi Akápò Ẹkùn, Yaya Adélékè Akowe owó fún Ẹkùn, àti Atofarati Olusanya gẹ́gẹ́ bíi Akọwe Alukoro Ẹgbẹ́, àti àwọn míràn.

Nínú ọ̀rọ̀ mo f’ara mọọ, Alhaji Ajísafẹ́ ṣèlérí láti máṣe ya kúrò nínú àlàkalẹ̀ àti òfin ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, nígbà to tẹnu mọ pé ẹgbẹ́ náà yóò gba àwọn ìpínlẹ̀ tó ku ní Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn, nígbà tó gbé oríyìn fún Gómìnà Makinde àti Adélékè fún àtìlẹ́yìn àti ọ̀rọ̀ iyànjú wọn.
O wá ṣèlérí láti sìn àti láti mú ẹgbẹ́ náà tẹ̀ síwájú.

Y

Ṣáájú ni Alága ìgbìmọ̀ olùdarí ètò ìdìbò ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn, to tún ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom, Udom Emmanuel ti gbé òṣùbà káre fún àwọn adarí àti àwọn èèkàn ẹgbẹ́ fún ìfọkànsìn àti akitiyan wọn eléyìí to ṣe òkùnfà ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ náà.

Lára àwọn tó wà níbí ìpàdé náà ni: ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ igbákejì Alága ẹgbẹ́ ni Ẹkùn Gúsù, Olóyè Olabode George; àwọn ìgbìmọ̀ majẹ́-kó-bàjẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP; àwọn ìgbìmọ̀ oṣiṣẹ ẹgbẹ́ ni Ẹkùn; àwọn ọmọ Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti Alága ìjọba ìbílẹ̀ láti Ìpínlẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà àti àwọn míràn.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button