Take a fresh look at your lifestyle.

12

 

Naomi Osaka Ní Àfojúsùn Fún Ìdíje Australian Open Bí Ó Tilẹ̀ Ní Ìfarapa

Ògbóntarigì agbábọ́ọ̀lù Tẹ́nìsì ọmọ orilẹẹ̀-ède Japan, Naomi Osaka yóò ṣe ayẹwo fún ifarapa to lee jade kuro nínú idije àsekágbá Auckland Classic sugbon o ni ifojusun to ga fún ìdíjé ti Australian Open, Olúborí idije Tẹ́nìsì agbaye atijọ náà ló sọ bẹẹ ni ọjọ́ Àjé.

Osaka, Olùborí ni odun 2019 ati 2021 ni
Melbourne Park, sun ẹkún ni ọjọ́ Àìkú nígbà ti ifarapa inú jẹ kó dágbére pe oun ko se mọ́ nígbà ti o ń fi agba hàn Clara Tauson pẹ̀lú ayo mefa sí mẹrin (6-4) nibi aseyege akọkọ re ti idije WTA final ni nǹkan bi ọdún mẹta ti o ti ṣẹlẹ rí.

Osaka padà fún eré lẹ́yìn ọdún kan sẹyìn latari isinmi aláboyún tó gbà ni o ti wà dáradára fún ìdíje to fún ni oore ọ̀fẹ́ láti gba àmì ẹ̀yẹ mẹ́rin ni ti ìdíje àsekágbá ni Auckland.

Ó padà sí ipò àwọn Àádọta àkọkọ ni àgbáyé ni ọjọ́ Ajé.

Ìdíje Australian Open yóò bẹrẹ ni ọjọ́ Àìkú.

Tèmítọ́pẹ́ Òbíisẹ̀san

Comments are closed.

button