Ile Isé VON Ba Ilé iṣẹ ìjọba FRCN Kẹ́dùn Ìjàmbá Ina Tó Sẹlẹ̀.
Ni orúkọ adari àgbà pátápátá fún ilẹ VON Mallam Jibrin Baba Ndace, èyí tí onimoero Maruff Kareem soju rẹ àti gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣé VON pátápátá ti ìlú Eko ló ba ilé iṣé FRCN kedun lórí ìjàmbá ina to o Sẹlẹ̀ sí wọn.
Ìjàmbá ina náà ti o bẹrẹ ni ago máàrún irọlẹ ni ojoru, ọjọ ketadinlogbon oṣù kọkànlá ọdun 2024, ti o sí Se akoba nlá fun gbogbo ilé iṣé náà
Wọn ní o Se àkóbá fún ọfisi marun ọ̀tọ̀tọ̀ àti àwọn ohun ìní àwọn òṣìṣẹ́ pẹlú.
Pẹlú bí iná náà ṣe gbilẹ to adari àgbà pátápátá fún ilẹ iṣẹ FRCN ni ìpínlẹ̀ èkó iyaafin Bolanle Omoyemi dupẹ lọwọ Ọlorun púpò nitori kò sí ení tí o pàdánù èmí rẹ lásìkò iṣẹlẹ náà.
Iyaafin Owóyemi ni orúkọ adari àgbà pátápátá fún ilẹ FRCN Dókítà Mohammed Bulama dupẹ lọwọ ilé iṣé VON fún aduro ti wọn ,o sí fi dà wón lójú àwọn yóò padà ṣí ipò laipe.