Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Iṣẹ́ Ọlọ́pàá Mú Afurasí Olè Màálù Méjì Pẹ̀lú Màálù Tí Iye Owó Orí Rẹ̀ Lé Ní Mílíọ̀nù Mẹ́fà Náírà.

17

Ilé Iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ìdarí Ọ̀gá Ọlọ́pàá Haruna Olufẹmi fẹ́ jẹ́ kí gbogbo aráàlú mọ̀ pé ọwọ́ ti tẹ àwọn ẹni méjì, Abu Muhammed àti Aliu Bello, tí wọ́n fura sí gẹ́gẹ́ bí olè màálù ní agbègbè Iresadu.

Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ṣe Alukoro ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá, DSP Ayanlade Olayinka ṣe ṣàlàyé pé lẹ́yìn ìròyìn tó tẹ wọn lọ́wọ́ nípa àwọn afurasí náà, ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹlú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ikọ elétò ààbò àdúgbò náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí eléyìí tó mú kí ọwọ́ tẹ àwọn ọ̀daràn meji náà.

Ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá nínú àlàyé rẹ̀ jẹ́ kó di mímọ̀ pé iṣẹ́ ìwádìí àkọ́kọ́ fi hàn pé àwọn afurasi náà ń gbìyànjú láti fi màálù tí wọ́n jí pamọ́ nígbà tí àwọn Ọlọ́pàá dá wọn dúró ní àlàfo Odojaye sí Aganyan, ní Iresadu, ti wọn sì gba màálù mẹ́rìndínlógún (26) padà, eléyìí tí a ṣe ìṣírò iye wọn sí ₦6,250,000.

Nígbà tí ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn afurasí náà, wọ́n jẹ́wọ́ pé wọ́n kópa nínú jíjì màálù, tí wọ́n sì pèsè àlàyé nípa bí wọ́n ṣe n ṣiṣẹ́ ibi wọn, ṣùgbọ́n àwọn Ọlọ́pàá ni iṣẹ́ ìwádìí ṣi ń tẹ̀ síwájú láti mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yòókù nínú ẹgbẹ́ olè náà àti láti gba àwọn màálù tí ó kù padà, lẹ́yìn èyí tí gbogbo àwọn tó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn náà yóò fojú ba ilé ẹjọ́.

DSP Olayinka wà tẹnu mọ́ pé elèyíi ṣe àfihàn pé ìfọwọ́sowọpọ̀ láàárín ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àti aráàlú ń mú èso rere jáde nípa ààbò ohun-ini àti ìgbé-ayé àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ilé Iṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá ni Orilẹ èdè Nàìjíríà, Kayode Egbetokun fún ìdarí àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀ eléyìí tó n ró iṣẹ́ Ọlọ́pàá lágbára káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Bakan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn agbègbè náà fún ìròyìn tó péye tí wọ́n fi ránṣẹ́ ní àkókò tó yẹ, èyí tí ó mú kí ilé iṣẹ́ Ọlọ́pàá pẹlú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ikọ elétò ààbò tí kii ṣe ti ìjọba bọ́ sójú iṣẹ́ ní kíákíá.

 

Abiola Olowe

Ìbàdàn

Comments are closed.

button