Osimhen, Lookman, Bassey Wà Lára Agbábọ́ọ̀lù Mọ́kànlá Ilẹ̀ Adúláwọ̀ Tó Dára Jùlọ Ti AFCON Ọdún 2025.
Àjọ Confederation of African Football (CAF), ti sísọ lójú eégún ní ojọ́ Ọjọ́rú agbábọ́ọ̀lù Mọ́kànlá Ilẹ̀ Adúláwọ̀ tó dára jùlọ ti AFCON Ọdún 2025 ti ikọ̀
Super Eagles orílẹ-èdè Nàìjíríà sì ní àwọn ògbóntàrigi akọni bíi
Victor Osimhen, Ademola Lookman, àti Calvin Bassey lára wọn.
Àwọn ikọ̀ ajo CAF tó yàn wọn ní – Technical Study Group (TSG).
Bí wọ́n ṣe dúró tipọ́n nìyí:

IKỌ̀ ÌDÍJE NÁÀ NÌYÍ;
Asọ́lé/Olọ́wọ́ ẹ̀mu.
Yassine Bounou (Morocco)
Àwọn Adeyinmú/Afọtamodi
Achraf Hakimi (Morocco)
Moussa Niakhaté (Senegal)
Calvin Bassey (Nigeria)
Noussair Mazraoui (Morocco)
Àwọn agbaboolu ipò aarin:
Ademola Lookman (Nigeria)
Pape Gueye (Senegal)
Idrissa Gueye (Senegal)
Àwọn agbaboolu ipò ọwọ iwaju:
Brahim Díaz (Morocco)
Victor Osimhen (Nigeria)
Sadio Mané (Senegal).
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san