Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Oyo Sàlàyé Bí Ẹ̀tọ̀ Ayẹyẹ Àádọta Ọdun Yóò Ti Lọ.

12

Ìjoba ìpínlẹ̀ Oyo ti sàlàyé bi àwọn ẹ̀tò yóò ti ló fún ayẹyẹ Àádọta ọdun ti wọn da ipinlẹ́ náà sílè.

Wọn ní lára re ni Gómìnà Makinde yóò ti da àwọn ẹlẹ́wọ̀n kankan silẹ ni àlàáfíà láti fi sààmì sí ajọdun náà.

Nìgbà ti o n ba àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ni ilè isẹ ìjoba ni Agodi ni ìlu Ibadan, Alága fún ajọdun ayẹyẹ àádọta ọdun to ti jẹ aṣoju ilẹ ìgbìmọ̀ aṣòfin tẹ́lẹ̀ rí Saheed Akinade Fijabi sọ wí pè ayẹyẹ náà yóò jẹ èyí ti yóò mú àlàáfíà ati ìrépọ̀ ba ìlú pàápàá jùlọ ìpínlẹ̀ Oyo lápapò.

Akinade Fijabi sọ wí pè àwọn ayẹyẹ bí àṣà,  isẹ́ ẹṣin, gbigba ààmì ẹ̀yẹ, ìdanilékọ̀ọ́, àṣẹ ife ni yóó wáyé lásìkò  ajọdun náà

Ó ni ààmì ẹ́yẹ ẹ́yẹ gbigba náà yóò wà fún àwọn ènìyàn ti o ti Sise takuntakun láti ri wí pè ìpínlẹ̀ Oyo dàgbà titi di àsìkò yìí

Ó ní àwọn ti fi iwẹ pé onile, ati alejò kakakiri àgbayé láti wa báwon ṣe ajọ yọ náà.

Ni ọjọ́ kẹta oṣù keji ọdún I976 ni wọn da ipinlẹ́ Óyo sílẹ̀

Comments are closed.

button