Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano Gbè Òsùbà O Kare Fún Àwọn Olópàá Bí Wọn Ṣe Mu Ìdàgbàsókè Bá Ètò Ààbò.

10

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abba Kabir Yusuf ti gbóríyì fún àwọn Ọlóopàá bí wọn ṣe mu ìdàgbàsókè bá ètò ààbò nì ìpínlẹ̀ kano.

Ó ni o jẹ ohun ìwúrí wí pè wọn dènà ìwà ìbàjẹ́ láàrin ìlú pàápàá jùlo bi wọn ṣe mu àwọn onise laabi ti pa ìyàwó ilẹ àti ọmọ mẹfa láì fi àkókò ṣofo rárá.

Gómìnà sọ èyí di mímọ̀ lásìkò ti o ṣe àbẹ̀wọ̀ sí olú ìlé isẹ àwọn Ọlóopàá ni Bompai nìgbà ti o bá Komísínà fún àwọn Ọlóopàá pàdé níbẹ Ibrahim Adamu Bakori.

Ó fi idunu re hàn bi ẹ̀ka ẹ̀tò ààbò ṣe n ló lọwọ báyìí ni ìpínlẹ̀ Kano ti iwa ìbàjẹ́ sí n di ohùn itan láàrin ìlú lápapò.

Ó ni ọ̀nà ti wọn gbà ṣíṣe náà jẹ ohun ìwúrí púpọ láìsí sí ìdá dúró rárá, Gómìnà ni fún ìdí èyí ohun tí Jabo fún Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíría Bola Tinubu ti èyí sí mu ki inú Ààrẹ dun púpò fún iṣé takuntakun náà.

Oga Ọlóopàá fún ìpínlẹ̀ Kano Ibrahim Adamu Bakori dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún àbẹ̀wọ̀ náà o sí ṣe ìlérí wí pè àwọn ko ni fàsẹhin nínú ìṣe àwọn láti ri wí pè ètò ààbò tẹsiwaju.

Comments are closed.

button