Take a fresh look at your lifestyle.

Àlàkalẹ̀ Ètò Fun Ayẹyẹ Àádọ́ta Ọdún Ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: Akinade-Fijabi Ni Ètò Gbogbo Ti Wà Ní Sẹpẹ́

23

Ẹni tii ṣe Alága ìgbìmọ̀ ayẹyẹ Àádọ́ta Ọdún ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Saheed Akinade-Fijabi tí jẹ́ kó di mímọ̀ pé ètò gbogbo ló ti wà ní sẹpẹ́ fún àyájọ́ ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Akinade-Fijabi lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé tí ìgbìmọ̀ náà ṣe pẹ̀lú àwọn oníròyìn, níbi tó ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ayẹyẹ náà yóò jẹ́ àsìkò ìdúpẹ́, ìrònú nípa àtiṣebọ̀ àwọn ètò iṣẹ́ ọpọlọ àti ọlọ́kan-ojọ̀kan ayẹyẹ àjọyọ̀ míràn.

Bákan náà ní Alága ìgbìmọ̀ ayẹyẹ tun ṣàlàyé síwájú pé ayẹyẹ Àádọ́ta Ọdún ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kii ṣe láti bu ọlá fún ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan olùgbé Ìpínlẹ̀ náà ti o ti lọ́wọ́ sí ìtàn àti àtiṣebọ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹ̀lú.

Nígbà to n ṣàlàyé, Akinade-Fijabi tẹnu mọ́ pé ètò ayẹyẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kínní ọdún yìí (26/01/2026) pẹ̀lú ìdánijẹ́kọ̀ọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ gíga Fafiti Ìbàdàn, tí gbogbo ètò yóò sì tẹnu bọdò ní ọjọ́ kẹta oṣù Kejì ọdún (03/02/2026) pẹ̀lú oúnjẹ alẹ́ nínú èyí tí ètò bíbu ọlá fún gbogbo ọmọ bíbí àti olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó ti lọ́wọ́ sí ìdàgbàsókè rẹ̀ yóò ti wáyé.

Alága ìgbìmọ̀ ayẹyẹ tun tẹnu mọ àwọn ètò míràn bíi ètò àyẹ̀wò ìlera ara ti yóò máa wáyé jákèjádò Ìjọba Ìbílẹ̀ Mẹtalelọgbọn (33) tó wà ni tìbú-tòró Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sinimọ́ ọfẹ ni àwọn ẹkùn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, eré ìdárayá, nígbà ti ètò ìrónilágbára fún àwọn obìnrin náà kò ní gbẹ́yìn.

Gẹ́gẹ́ bí Alága ìgbìmọ̀ ayẹyẹ naa se sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó fi lédè pé ìjọba yóò sí gbàngàn ìbu ọlá fún àwọn olókìkí (Hall of fame) ni Sekiterati Ìjọba láì pẹ́, níbi tí wọn yóò ti máa ṣe àfihàn ìtàn àṣeyọrí àti àwọn tó lọ́wọ́ sí ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ìgbà ìdásílẹ̀ rẹ̀.

Alága ìgbìmọ̀ wá ṣe àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó fi ye àwọn oníròyìn pe, ayẹyẹ náà kìí ṣe fún ẹgbẹ́ òṣèlú kan pàtó, nítorí gbogbo ènìyàn láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú yìówù náà ni yóò kópa nínú ayẹyẹ ná.
Látàrí èyí, ni ìpè ṣe lọ káàkiri láti ke sí ará, ọrẹ àti gbogbo ènìyàn ní igun mẹrẹrin àgbáyé láti wá jẹ́ alábàápín nínú ayẹyẹ Àádọ́ta Ọdún ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àkọlé ayẹyẹ náà ní “Mímọ le ogún rere, Líla ipa fún ọjọ́ òní, àti Ìrònú nípa ọjọ́ ọ̀la” (Consolidating the Legacy, Navigating the Present, and Reimagining the Future).

Abiola Olowe.
Ìbàdàn

Comments are closed.

button