Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Àpapọ̀ àwọn Ọmọ-ogun ní Ìwọ̀-Oòrùn Àríwá tí á mọ́ sí ‘Operation FANSAN YAMMA’, ti ní àṣeyọrí tuntun nípa pípa àwọn Àpániláyà ní Ìpínlẹ̀ Kebbi tí wọ́n sì gba àwọn méjìlélọ́gọ́ta (62) tí wọ́n jigbé ní Ìpínlẹ̀ Zamfara la.
Àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ní wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ààbò àti àwọn ọmọ-ogun ìbílẹ̀, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ láti kojú àwọn onijakidijagan àti àwọn ajínigbé ní Ìwọ̀-Oòrùn Àríwá.
Comments are closed.