Alága Ìgbìmọ̀ Eré-ìdárayá tí Orilẹ-ede (NSC), Shehu Dikko, sọ pé gbogbo ẹ̀tọ́ ìnáwó ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Super Eagles àti àwọn aláṣẹ ní wọ́n ti yanjú.
Ọ̀rọ̀ Dikko tẹ̀lé àwọn ìròyìn nípa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Super Eagle tí wọ́n ń halẹ̀ láti má ṣé kópa nígbà ìdánrawò àti ìrìn àjò lọ sí Marrakech fún ìdíje African Cup of Nations (AFCON) ní ọjọ́ Àbámẹ́ta pẹ̀lú Algeria.

Alaga náà sọ pé Ààrẹ Bola Tinubu ti fọwọ́ sí ìṣúná owó AFCON 2025 ti Super Eagles láti oṣù kọkànlá ọdún 2025, pẹ̀lú ìlànà àtúnṣe sí NSC, NFF àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà.
Ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé pé ìfọwọ́sí àti ìtọ́jú náà jẹ́ àwọn ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n ó fi dá àwọn agbábọ́ọ̀lù náà lójú pé wọ́n ti fọwọ́sí owó àti pé wọ́n tí bẹ̀rẹ̀ sí sán rẹ̀.

Ẹgbẹ́ Super Eagles ti ṣẹ́gun gbogbo àwọn ìfẹsẹ́wọnsẹ̀ wọn títí di ìsinsìnyí, wọ́n sì gba góólù méjìlá wọlé (12 goals) nígbà tí wọ́n tí peregede sí ipele ẹlẹni-mẹ́jọ.