Látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù àwọn agbébọn sí àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ìtọ́jú ẹranko àtijọ ni Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ènìyàn agbègbè náà láti ṣe sùúrù.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù àwọn agbébọn eléyìí ti Alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, DSP Olayimika Ayanlade jẹrìí sí nínú èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ márùn ti pàdánù ẹ̀mí wọn, lo wáyé ni Abúlé Oloka, ni Ìjọba Ibilẹ Oríire.
Gómìnà Makinde, gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde ti Olùdámọ̀ràn pàtàkì rẹ̀ fún ìròyìn, Sulaimon Olanrewaju fi ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn ni ìlú Ìbàdàn tii ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló ṣèlérí pé ìṣèjọba òun yóò ṣe ohun gbogbo to yẹ láti ri dájú pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹẹ kò wáyé mọ́.
Gómìnà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kóró ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nígbà tó jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ náà n se ojúṣe wọn lásìkò tí ikọlu náà wáyé, o wa gbàdúrà ki Ọlọrun tẹ wọn sì afẹ́fẹ́ ire.
Àtẹ̀jáde náà tún ṣàlàyé pé àwọn òṣìṣẹ́ eleto ààbò tí fọwọsowọpọ láti wá ojútùú sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, nígbà tí wọn pè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn agbègbè náà fún àṣeyọrí iṣẹ́ ìwádìí wọn.
Abiola Olowe.
Ìbàdàn