Agbábọ́ọ̀lù Liverpool, Hugo Ekitike ní Olùkọ́ni Liverpool Arne Slot tí ń ṣiyèméjì pé òun kò rò bóyá yóò gbá bọ́ọ̀lù fún ikọ rẹ̀ ní Ọjọ́bọ̀ nígbà tí Arsenal bá gbàlejò wọn nínú ìdíje Premier League latari ìfarapa.
Ekitike, ẹni tó tí gbá góólù mẹ́jọ wọlé ní àsìkò yìí, pàdánù ìfàsẹ́yìn ní ọjọ́ Àìkú nígbà tí fẹ́sẹ́wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú Fulham yọrí sí 2-2 nítorí òun tí Slot pè ní ìpalára díẹ̀. Àti pé Arne Slot náà sọ pé àkókò ń lọ fún agbábọ́ọ̀lù náà láti múra sílẹ̀ bí Liverpool yóò ṣé kojú Arsenal.

Àìsí Ekitike yóò jẹ́ ìjákulẹ̀ mìíràn fún Slot, ẹni tí kò ní Alexander Isak nítorí ìpalára àti Mohamed Salah nítorí ìdíje ‘African Cup of Nations’.