Manchester United ti lé olùkọ́ni Ruben Amorin kúrò nínú ikọ́ wọ́n, ẹgbẹ́ náà sọ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kan lẹ́yìn tí wọ́n tá ọmi nínú ìdíje English Premiership.
Manchester United tí wà ní ipò kẹ́fà lórí akásọ ìdíje náà, tí wọ́n sì borí ọ̀kan nínú àwọn ifẹsẹwọsẹ márùn-ún tó kẹ́yìn.

Amorin ọmọ ogoji ọdún náà tó tabuku àwọn oníròyìn kúrò pẹ̀lú ìbáwí líle koko nípa “yíyàn oríṣi agbábọ́ọ̀lù nígbà kúgbà” kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà ipò rẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú.

Amorin sọ ọ́ di mímọ̀ pé kò ní èrò láti kúrò ní Old Trafford, ó ń tẹnu mọ́ àṣẹ ìṣàkóso rẹ̀ lórí àwọn iṣẹ́ olùkọ́ni lásán.