Àwùjọ Ètò-ọrọ-àjé tí Àwọn Orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà (ECOWAS) sọ pé àwọn wó idagbasoke túntún tí ń lọ́ ní Orílẹ̀-èdè Venezuela pẹ̀lú àníyàn nlá.
Gbólóhùn kan lati ọdọ Igbimọ ECOWAS sọ pe òun mọ́ pé ẹtọ wà láti kojú awọn òun ti kò tọ́ bí ipanilaya àti gbígbé oogun olóró, ṣùgbọ́n Igbimọ fẹ lati jẹ́ ki gbogbo àgbègbè agbaye wó ojuse wọn láti bọwọ fún ìjọba àti agbegbe rẹ̀”, gẹgẹ bí a ti fi sinu ofin agbaye.
Gbólóhùn naa fi kun: “ECOWAS fara mọ gbólóhùn ti Ẹgbẹ́ Ajọ Afirika AU tó pe fun ìdádúró àti ìjíròrò àpapọ̀ láàrin àwọn ènìyàn Venezuela.”
Igbimọ ECOWAS wá tun rọ àti kẹ́dún pẹlu àwọn ènìyàn Venezuela o si rọ gbogbo Àwọn Orílẹ̀-èdè láti bọwọ fún òmìnira àti ìṣọ̀kan agbègbè ti Venezuela” o si ṣé àfihàn àtìlẹ́yìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn bí wọ́n ṣe n gbèrò ọjọ́ iwájú orílẹ̀-èdè wọ́n.