Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí pàṣẹ fún Mínísítà fún ààbò, Olórí Àwọn Ológun, Àwọn Olórí Gbogbo Àwọn Ọmọ Ológun, Olórí Àwọn Ọlọ́pàá, àti Olùdarí Àgbà ti Ẹ̀ka Àwọn Iṣẹ́ Ìpínlẹ̀ (DSS) láti wá àwọn tó ṣe ìkọlù sí Kasuwan Daji kí wọ́n sì mú wọn ní kíákíá láti fojú wọ́n bofin.
Ó tún pàṣẹ fún àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò láti gbá gbogbo àwọn tí wọn jí gbé pàdà ní kíákíá.
Ààrẹ Tinubu pàṣẹ ní ọjọ́ Àìkú ní ìdáhùn sí ìpànìyàn àwọn aráàlú ní Ìpínlẹ̀ Niger tí àwọn apanilaya tí wọ́n fura sí pé wọ́n ń sá láti Sokoto àti Zamfara lẹ́yìn ìkọlù òfurufú Amẹ́ríkà ní alẹ́ ọjọ́ Kérésìmesì ti kọjá.
Nínú ìkéde kan tí Agbẹnusọ Ààrẹ, Bayo Onanuga, Ààrẹ dẹ́bi ìkọlù sí Àwùjọ Kasuwan Daji àti jíjí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé gbé.
Ó fi ìkẹ́dùn ọkàn rẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ìdílé àwọn tó kú, àti sí Ìjọba àti àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Niger.