Lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n ti mú un, ilé ẹjọ́ gíga orílẹ̀-èdè náà ti kọ̀ láti gbá òní’dúró alátakò Ìjọba Ùgándà Kizza Besigye kúrò nínú túbú.
Wọ́n ti fi ẹ̀sùn ìṣọ̀tẹ̀ kan Besigye nítorí pé ó gbèrò láti fi agbára mú ààrẹ Yoweri Museveni ti orílẹ̀-èdè náà kúrò.
Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́, ó sọ́ pe àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án jẹ́ tí inúnibíni.
Ọmọ ọdún méjìdínlaadọrin (68) náà ti wà ní àhámọ́ láti oṣù kọkànlá ọdún 2024 nígbà tó sọnù ní Olúìlú Kenya, Nairobi.
Àwọn amòfin kan sọ pé wọ́n ń kọ̀ láti gbá òní’dúró rẹ̀ àti tí àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn ní Uganda; lára wọn ni Sarah Bireete, Olùdarí Àgbà ti Ilé-iṣẹ́ Ìjọba Tiwa-n-tiwa (Center for Constitutional Governance).
Ìpinnu ilé ẹjọ́ náà wáyé ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ kí Uganda tó ṣe ìdìbò gbogbogbòò rẹ̀.
Ààrẹ Museveni, tó ti wà ní ipò Ààrẹ láti ọdún 1986, ni a ń retí pé yóò jáwé Olubori nínú ìdìbò tó ń bọ̀, èyí tí yóò fún un ní ọdún márùn-ún mìíràn lórí ipò agbára.