Take a fresh look at your lifestyle.

Olóyè Pàtàkì Ni Ile Ẹjọ Gíga  Jùlọ Rọ Awon Adájọ Láti Se Ìdájọ Pèlú Àánú.

45

Olóyè Pàtàkì  ni ilé ẹjọ́ gíga jùlo ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Kabir Akanbi ti rọ àwọn adájọ kàkàkí Orílè-èdè Nàìjíríà láti ṣe ìdájọ pèlú Àánú lójú.

Nígbà tí o ṣe Ẹgbẹ́ àwọn adájọ ti ìlú Abuja ( NAJUC) se ìbẹ̀wọ̀ sí Akanbi ni o ti rọ wọn láti fi Àánú kún ìdájọ wọn.

Ó sàlàyé wí pé ọpọlọpọ nkán ni o n ṣẹlẹ̀ ni ori aféfé báyìí nibi ti àwọn ènìyàn ti  ṣe ìdájọ ni ọna ti ko tó ti kò sí yé ko rí béè labẹ ìjọba awarawa.

Akanbi pé fún irẹpọ láàrin àwọn adájọ àti àwọn amofin ki ìdàgbàsókè ba le ba ètò ìdájọ

Alága NAJUC ti Abuja Ọ̀gbẹni Kayode Lawal dupẹ lọwọ Akanbi bí o ṣe gba wọn là lejò

Ó sí fí da àwọn ènìyàn lójú wí pé ni ètò ìdájọ àwọn n gbìyànjú fún ìdájọ to péye.

Comments are closed.

button