Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò Ẹ̀kọ́: Ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Rẹmi Tinubu Bèrè Anfààní Ẹ̀kọ́ Ọfẹ Fún Àwọn Ọ̀dọ́.

49

Ìyàwó Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Oluremi Tinubu, sọ wí pé oun ṣiṣe lórí bí ètò ẹ̀kọ́ ọfẹ yóò ṣẹ wa fun àwọn ọ̀dọ́

Nígbà tí o ń ba aláṣẹ ilé iṣé MERCK Foundation sọ̀rọ̀, ilé iṣé ti o jẹ aláàdáni láti Orílẹ̀-èdè German nígbà tí wọn ṣe àbẹ̀wò sí ni ìlú Abuja.

Ìyàwó Ààrẹ ṣe àpèjúwe ètò ìlera àti Ẹ̀kó lohun tó jẹ pàtàkì jùlọ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Labe ètò ìjọba Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu.

Nibe ni o ti sàlàyé pàtàkì èròngbà rẹ láti rí wí pé àwọn ọ̀dọ́ rí anfààní sí ètò ẹ̀kọ́ ọfẹ.

Ó gbóríyìn fún ilẹ isé náà fún ìrànlọ́wọ́ ètò ẹ̀kọ́ ọfẹ ti o ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti yóò ko ẹ̀kó nípa iṣé Oníṣègùn òyìnbó ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Alaga, ilé iṣé MERCK Foundation, Ọmowé Frank Strangenberg-Haverkp ati àwọn òṣìṣẹ́ ṣe ìbẹ̀wọ̀ sí ìyàwó Ààrẹ látari akitiyan rẹ láti rí wí pé àwọn ọ̀dọ́, Obinrin àti àwọn ọmọdé ni anfààní sí ètò ẹ̀kọ́ ọfẹ.

Wọn wá gbé Òsùbà o Kare fún ìyàwó Ààrẹ fún iṣé takuntakun náà

Comments are closed.

button