Take a fresh look at your lifestyle.

Àṣìta Ìbọn: Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Kẹ́dùn Pẹ̀lú Ìdílé Ọ̀dọ́mọdé-kùnrin Kan Tó Pàdánù Ẹ̀mí Rẹ̀

80

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ìṣàkóso Gómìnà Seyi Makinde ti bá ìdílé ọ̀dọ́mọdé-kùnrin kan to pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ látàrí àṣìta ìbọn.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí fi aidunnu rẹ̀ hàn sí ìṣẹ̀lẹ̀ àṣìta ìbọn náà eléyìí tó gba ẹ̀mí ọmọkùnrin kan to nlọ ṣe ìdánwò WAEC, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá to n mójú tó ìgbòkègbodò ọkọ̀ lójú pópó ni agbègbè Alakia yin ìbọn sí táyà ọkọ̀ kan ṣùgbọ́n tí ọta ìbọn náà ṣeesi lọ bá ọmọ náà nínú ọkọ̀ to wà.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ nígbà to rawọ́ ẹbẹ sí àwọn ènìyàn tó bínú ya wọ Sekiteriati ìjọba lọ láti fi ẹ̀hónú wọn hàn, ti ìjọba sì ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé ìṣẹ́ ọlọ́pàá láti wadii ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti láti gba ìdájọ́ òdodo.

Nígbà ti ọkan lára àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ naa ṣojú rẹ̀ n fìdí rẹ̀ múlẹ̀, o ṣàlàyé pé bàbá ọmọ to pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ náà ló wà ọkọ̀ ayọkẹlẹ (Honda Accord, pẹ̀lú nọmba ìdánimọ̀ FST 639 JU) gba ọ̀nà ti kò tọ́, nínú èyí tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó dáa dúró ṣùgbọ́n tí kò dúró, kí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà to yin ìbọn sí táyà ọkọ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n ti ọta náà wọlé si ará ọmọ náà tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.

Ìjọba wa rawọ́ ẹbẹ sí àwọn ènìyàn láti fún wọn ní anfààní ki ìjọba àti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wa ojútùú sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. O wá kìlọ fún ará ìlú láti yàgò fún ṣíṣe lòdì sí òfin ìrìnnà ojú pópó.

Bákan náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣàlàyé pé lòdì sí ohun tí ọpọlọpọ ará ìlú n sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá lọ yin ìbọn lásìkò tí wọn n le àwọn ọmọ Yahoo, nígbà tó tẹnu mọ́ọ pé àwọn òṣìṣẹ́ OYRTMA, pẹ̀lú ìkọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà ló n ṣe iṣẹ́ ìríjú wọn látàrí bí àwọn olùgbé agbègbè náà ṣe máa n lòdì sí òfin ojú pópó eléyìí to n ṣokùn fa ìjàmbá to n la ẹ̀mí lọ lọpọ ìgbà.

Bẹẹ náà ní ìjọba mú wa sí ìrántí àwọn ènìyàn náà pé, lójúnà àti jẹ́ kí àwọn awakọ̀ tẹ̀lé òfin ìrìnnà ni àwọn òṣìṣẹ́ OYRTMA to n mójú tó lílọ àti bíbọ̀ ṣe wa ni àwọn ojú pópó ṣùgbọ́n tí awakọ̀ kan tó tako òfin ìrìnnà ṣe ikú pa ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ OYRTMA náà laipẹ yìí.

Abiola Olowe
Ìbàdàn.

Comments are closed.

button