Ìpínlẹ̀ Ogun ti sọ pé àwọn yóò fi ẹwà Àṣà, Ìrìnajo-afẹ́ wọn hàn fáráyé látàrí àjọ̀dun Ìdíje eré ìdárayá Ẹlẹ́ẹ̀kejìlélógún National Sports Festival (NSF), tí wọ́n pè ní “Gateway Games” to ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Abeokuta.
Ọ̀gbẹ́ni Dare Odufowokan, olùrànlọwọ àgbà pàtàkì fún Gómìnà lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ fún àwọn ènìyàn ló sọ èyí ní ọjó Ajé ní ìlú Abeokuta.
Ó sọ pé àjọ̀dún eré ìdárayá kìí ṣe fún eré ìdárayá nìkan ṣùgbọ́n ó jẹ́ ànfààní láti polongo ìtèsíwájú àṣà àjogúnbá àti àlejòsíse wọn.
“Àjọ̀dún eré ìdárayá kí ṣe ti ìdárayá nìkan, ṣùgbọ́n ọnà láti ṣe ayẹyẹ àṣà wa, ìtèsíwájú ìṣọ̀kan, ìmúgbóòrò ìrìnajo-afẹ́”, ó sọ èyí.
Alága àjọ NSF Media Sub-Committee, Adekunle Solaja, wà pe àwọn oníròyìn láti polongo àjọ̀dún ìdíje náà, kí wọn ri bí ọnà láti jẹ kí eré ìdárayá dàgbà síi àti ọ̀nà láti wà iṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́.

Àjọ̀dún ìdíje náà ló bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún, yóò sì pari ní ọgbọnjọ́ oṣù yìí
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san