Take a fresh look at your lifestyle.

FRSC J’àbọ̀ Adínkù Ìjàmbá Ọkọ Ṣùgbọ́n Ìjàmbá Olóró Ń Pọ Sí

Lekan Orenuga

225

Àwọn Ẹ̀ṣọ Ojú Pópó Tí Ìjọba Àpapọ̀ (Federal Road Safety Corps FRSC) tí j’àbọ̀ ìròyìn adínkù ìdá mẹ́wàá 10% lápapọ̀ àwọn ìjàmbá òpópó-ọ̀nà láàrin ọdún 2023 àti 2024, sùgbọ́n ìdá méje 7% ní àwọn tó f’ara gbá ìjàmbá náà tó kú.

‎ Corps Marshal Shehu Mohammed ló sọ èyí lásìkò ìṣẹlẹ kán látí ṣé ìrántí Ọsẹ Ààbò Òpópó-ọ̀nà Àgbáyé kẹjọ tí Àjọ Àgbáyé (United Nations).

‎ Gẹ́gẹ́ bí Mohammed tí sọ, FRSC ṣé àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn 31,154 tó f’ara pa nínú ìjàmbá òpópó-ọ̀nà láàrin ọdún 2024 nìkàn.

‎ O tẹnumọ pé àwọn ìṣirò náà kọjá onka lásán, ó ṣàfihàn àwọn ẹmi tó sọnù, àwọn ìdílé àti àwọn àgbègbè to kàn.

‎ Mohammed ṣé ìdánilójú pé FRSC yóò tẹ̀síwájú látí fí ipá mú àwọn idiwọn iyàrá ilú fún àwọn ọkọ ayọkẹlẹ, ní ìlànà pẹ̀lú Àjọ Àgbáyé fún Ìlera (WHO).

Comments are closed.

button