Take a fresh look at your lifestyle.

Àtúntò Ètò-Ẹ̀kọ́ Ààrẹ Tinubu Fún Ọjọ́-Iwájú Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́

Lekan Orenuga

90

Bí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gbé ìgbésẹ akin lórí àtúntò Orílẹ̀-èdè, ìṣàkóso Ààrẹ Bola Tinubu gbé ètò-ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè ọgbọ́n sí ọkàn nínú èro ìyípadà àti àtúntò rẹ̀.

‎ Ètò ìmúlò Ètò-Ẹ̀kọ́ lábẹ́ Ètò Ìrètí Túntún ṣé pàtàkì ànfàní, ètò dídára ati ìbámu, pẹ̀lú idojukọ sáyẹ́nsì, àwọn Imọ-ẹrọ ati Ìṣirò (Science, Technology, Engineering and Mathematics STEM) atí ìkẹ́kẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ gẹgẹ bí àwọn irinṣẹ́ láti fún àwọn ọdọ ní agbára látí fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ Nàìjíríà ni agbára lọjọ̀ iwájú.

‎ Ààrẹ Tinubu ti tẹnu mọ́ ọn lemọ́lemọ́ pé àwọn ènìyàn tó kàwé àti àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ní gbòngbò ìdàgbàsókè. Ìfaramọ́ tí ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ àfihàn ìlànà àtúnṣe ètò-ẹ̀kọ́ tó kún, pẹ̀lú ṣiṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga, imọ-ẹrọ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ ọwọ́, ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn olùkọ́.

Comments are closed.

button