Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí n ṣé àfihàn ìgbésẹ̀ àtúnṣe tí Òfin Ọọ̀ràn-Orí-Ayélujára, gẹ́gẹ́bí Mínísítà fún ìròyìn àti Àlàyé tí Orílẹ̀-èdè, Mohammed Idris, ṣé ìdánilójú imurasilẹ ìjọba láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin tí Orílẹ̀-èdè, àwọn oníròyìn, àti àwọn alabaṣepọ pàtàkì mìíràn nínú ìlànà àtúnyẹwò òfin náà tí nlọ́ lọwọ́.
Mínísítà náà kéde èyí lẹ́yìn ìpàdé kán pẹ̀lú Richard Mills, Aṣojú America sí Nàìjíríà, ní ọfiisi rẹ̀ ní Abuja.
Mínísítà náà tẹnumọ pé èròngbà tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yìí ní láti ṣé ìdàgbàsókè òfin tó ní ifọkanbalẹ tó gbòòrò, tí yóò tún jẹ́ itẹwọgbà fún gbogbo àwọn tó kàn.

Ní iṣáájú, Aṣojú America sí Nàìjíríà, Mills, sọ pé ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú Mínísítà jẹ́ èyí tó nípa, pàápàá lórí àwọn ọran tó jọmọ òmìnira ìròyìn àti ipá pàtàkì tí Ilé-iṣẹ́ ìròyìn àti àlàyé yóò ṣé nínú àtúnyẹwò tí n bọ̀ lórí Òfin àti Irúfin Ayélujára.
O tún ṣé itẹwọgbà àlàyé Mínísítà tí a gbe jade ní Ọjọ́ Òmìnira àwọn Oníròyìn Àgbáyé, èyítí o tún jẹ́ ìfaramọ́ tí ìṣàkóso Ìjọba Ààrẹ Tinubu láti ṣé àtìlẹ́yìn Òmìnira ìròyìn.
Comments are closed.