Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Gbé Òsùbà O káre Fún Oníròyìn Àgbà Bisi Olatilo Fún Àádọta Ọdún Lẹnu Iṣé Ìròyìn.

49

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu ti gbé Òsùbà o káre fún Aláṣẹ àti Olùdarí ilé iṣé Biscom Communication, Ọmọba Bisi Olatilo fún ayẹyẹ àádọta ọdún lénu iṣé ìròyìn.

Ààrẹ gbóríyìn fún ọmọba Olatilo fún akitiyan, ipá mọra, ìfẹ àti àlàáfíà tó ń wà fún ìdàgbàsókè Orílè-èdè Nàìjíríà láti àádọta ọdún to ti wa lenu iṣé.

Nínú àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ Olubadamoran fún òrò tó n ló lafefe, Ọ̀gbẹni Bayo Onanuga, Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe àpèjúwe ilé iṣé náà gẹ́gẹ́ bí ilé iṣé tó n  wa ìdàgbàsókè Orílè-èdè Nàìjíríà.

Ààrẹ Wa ba Bisi Olatilo ṣe ajoyọ àti akitiyan rẹ láti rí wí pé ìdàgbàsókè ba ọrọ Orílẹ-èdè Nàìjíríà.

Nigba ti Ààrẹ Tinubu gbóríyìn fún Bisi Olatilo, Ààrẹ tun mẹnu ba ètò rẹ tí ó wọn ọdún marundinlogbon lórí aféfé, Aare ni ètò jẹ èyí tí ko fi àlàfo sí àárín ẹṣin àti ìlú.

Lakotan Ààrẹ Tinubu ki Bisi Olatilo fún ayẹyẹ ọjọ-ibi Mọ́kànlẹ́làádọ́rin lori èpè.

Comments are closed.

button