Alága àjọ Nigerians in Diaspora Commission, NiDCOM, Dókítà Abike Dabiri-Erewa gbósùbà ràbàndẹ̀ fún odomobirin ọmọ ọdún Mejila, Amazing-Grace Ahuoyiza Ebiebi Salami tó gbégbá orókè níbi iside ìdíje ẹkọ Spelling Bee In Nigeria (SpIN), ti yóò sì lọ sojú orilẹ̀-ède Nàìjíríà nbi ìdíje Scripps National Spelling Bee ní Washington, D.C ti Ọlọ́gọ̀rún irú rẹ ìdíje oníyì náà.
Alága àti adari àjọ Nigerians in Diaspora Commission, NiDCOM, naa, Dókítà Abike Dabiri-Erewa ṣàpèjúwe àseyege rẹ̀ gẹgẹbi èyí to buyi kun Nàìjíríà, ìyí apapọ ló jẹ . Òun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Ghana ní yóò lọ sojú ilẹ̀ Adúláwọ̀ níbi ìdíje tó gbayì náà láti ìgbà tí wọn ti dáa silẹ ní nǹkan bí Ọgọ́ọ̀rún ọdún sẹyìn.
Nigba ti wọn ṣe abẹwo ọlọlá- sì Olu ìlú ise NiDCOM ní Abuja, Salami fi idunnu rẹ hàn fún àṣeyọrí rẹ àti fún ìdíje tó ní bọ̀, pé yóò fún òun ní anfààní láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ bí ti òun ní àgbáyé.
Ó wá dúpẹ fún atilẹyin ti òun rígbà, ó si ṣèlérí láti tun fakọyọ ní àgbáyé láti túbọ̀ gbé ògo Nàìjíríà ga sì. Ìyá rẹ, Iyaafin Kemi Salami, Eugenia Tachie-Menson to jẹ adari orílè-èdè fún Young Educators Foundation ló ṣáájú ìkọ náà àti àwọn ènìyàn miran jọ kọ̀wọ́ rin pẹlu rẹ̀ níbi ètò oríire náà.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san