Aya Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Olurẹmi Tinubu ti kí àwọn òsìṣẹ́ jákè-jádò Orílẹ̀-èdè kú oríire ní àyájọ́ tí a yàn láàyò fún wọn
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, aya Ààrẹ gbósùbà fún wọn látàrí ìfarajì àti ipa ribiribi tí wọn ń kó fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè
Ó sàpèjúwe àwọn òsìṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ fún Orílẹ̀-èdè àtipé ipa wọn kò kéré nínú ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé