Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin pàrọwà Sí Ìjọba Láti Fún Àwọn Ilé Iṣé Ìròyìn Lágbára Ní Ìpínlẹ̀ Sokoto
Ilé ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ̀ Sokoto ti pàrọwà sí ìjọba Ìpínlẹ̀ náà láti fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn lágbára pẹ̀lú ìpèsè àwọn ohun èlò tí ó yẹ, èyí tí yóò mú kí ọwọ́jà wọn kárí ilé- kárí oko
Alhaji Sa’idu ni ó fi àbádòfin náà léde, ẹni tí ó ń sojú àgbègbè Sabon Birni, nígbà tí Awaisu Aliyu kéjì rẹ̀, níbi ìjókòó ilé asòfin tí ó wáyé
Ibrahim sàpèjúwe ìdákú-rekú amóhùn-máwòrán àti ilé iṣẹ́ Asọ̀rọ̀mágbèsì ti ìjọba Ìpínlẹ̀ Sokoto ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyè gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò dára tó, tí kò sì fún àwọn ènìyàn ní ànfààní láti gbọ́ àwọn ètò ìjọba, èyí tí yóò jẹ́ kí wọ́n mọ bí gbogbo nǹkan se ń lọ
Ó wá pè fún àtúnṣe àti ìpèsè àwọn ohun èlò ìgbàlódé, èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ní Ìpínlẹ̀ Sokoto