Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sàfihàn ìfarajì rẹ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìkópa àwọn ọ̀dọ́ nínú ètò ìsèjọba, ìdàgbàsókè ìgbèríko gẹ́gẹ́ bí àwọn ìgbésẹ̀ tí yóò jẹ́ kí àlàáfíà jọba ní Orílẹ̀-èdè Naijiria
Mínísítà Fún Ìdàgbàsókè Àwọn Ọ̀dọ́, Ayọdele Ọlawande ni ó fi àrídájú náà léde nígbà tí ó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ rẹ̀ níbi àpérò kan èyí tí àwọn ọ̀dọ́ se agbátẹrù rẹ, tí ó wáyé ní Ìpínlẹ̀ Nasarawa
Ọlawande, ẹni tí Olóyè Obinna Nwaka sojú fún sọ pàtàkì àwọn ọ̀dọ́, wọ́n jẹ́ adaŕi lọ́la àtipé ojúse wọn fún àtúntò, ìdàgbàsókè, ààbò àti àlàáfíà ìlú jẹ́ ohun pàtàkì àti ìwúlò àwùjọ