Mínísítà Òsìṣẹ́ Àti Ìgbanisíṣẹ́, Mohammed Dinyadi ti dáwọ̀ọ́ ìdùnnú pẹ̀lú àwọn òsìṣẹ́ ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ àwọn òsìṣẹ́ se ń lọ lọ́wọ́ ní àgbáyé
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sàlàyé pé gbígbé òsùbà fún àwọn òsìṣẹ́ jẹ́ ohun tí ó tọ́ nítorí ipa ribiribi tí wọn ń kó fún ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè
Ó tẹ̀síwájú pé ìjọba mọ rírì àwọn òsìṣẹ́, yóò sì tẹ̀síwájú nínú ojúse rẹ̀ láti se kóríyá àti ìpèsè ohun ìgbáyégbádùn fún wọn