Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n Dá Àwọn Ọmọ Ẹgbẹ́ IPOB Sílẹ̀

143

A-jà-fún-ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn àti agbẹjọ́rò, Sa, Ifeanyi Ejiofor
ti sọ pé òtítọ ní pé wọn ti da àwọn Méjìlá ọmọ ẹgbẹ́ Indigenous People of Biafra (IPOB) ti wọn wà ní àtìmọ́lé láti ọjọ́ kerinlelogun osu karun ọdún 2021, sile láti ọwọ́ ilé ẹjọ gíga ipinlẹ Ebonyi.

Bí ọgbẹni Ejiofor ṣe sọ, bí wọn ṣe da wọn sílẹ yá lati ọwọ ọ̀gá àgbà ipinlẹ Ebonyi to wà fún ètò ìdájọ Ọmọnìyàn ti Macfred Ezike sojú fún, lo da ẹ̀sùn gbogbo ti wọn fi kan wọn nù bí omi ìsanwọ́ fún idasilẹ wọn.

Agbẹjọro náà ní ìgbàgbọ́ pé àwọn tó kú ní àhámọ́ máa jade laipẹ nitoripe wọn ti dáwọn sílẹ ní aláafia láti ọwọ́ ilé ẹjọ gíga mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.

Nínú àkọsílẹ̀ lẹyin ìdásílẹ́ wọn, Ejiofor sọ pé, ìdájọ leè pẹ́, ṣugbọn ododo ní yóò leke, ẹtọ àwọn ènìyàn wọn kò ní fi dùn wọ́n.

O fi kun pe, ìdásílẹ́ àwọn Biafra méjìlá yìí lẹyin ọdún mẹrin ní àtìmọ́lé sàmìn sí àseyege ìdájọ òdodo àti ẹ̀tọ́ ẹni-kọọkan sì ìdájọ òdodo.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button