Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀pọ̀ Èwe Dojúkọ Ìpáǹle Ìbánisùn Ní Àríwá Congo- UNICEF

213

Bí àjọ UN ṣe sọ, àwọn ọdọmọde, ewé ti wọn kò ìdá kan o lé nínú ẹgbẹrun mẹwa ẹ̀sùn ìbánilòpọ̀ àwọn ọmọdé ni wọn n ṣe tìpá tì ìkúkùù ìbálòpọ̀ fún ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Congo ni ìbẹrẹ oṣù méjì ọdún yìí.

Bí agbẹnusọ àjọ UNICEF, James Elder ṣe sọ, Ibalopọ àìfaramọ́ àti ẹ̀sùn Ìpáǹle ìbálòpọ̀ miran ní wọn n lò bí ohun ìjà ogún ti o si n waye ni iṣẹju iṣẹju mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, ti àwọn ọmọdé ti wọn ṣẹṣẹ ń rin sì wà lára àwọn ti wọ́n ń bá lòpọ̀.

“Ohun ìjà ogún nìyí, ọgbọ́n àtinúdá ìjà ibi burúkú ti wọn mọ̀ọ́mọ̀ sì ni.”

Ìkọ ọmọ ogún ọlọtẹ M23 gba apá kan Ilẹ Àríwá Congo ni ìbẹrẹ ọdún yìí láti dojú ìjà tó lágbára kọọ́, ọpọ ènìyàn ló ti fẹsẹ̀ fẹ ti wọn ti sá kúrò nílé wọn, ti wọn ti kú àti ọmọdé àtàgbà.

Bí ọ̀gbẹ́ni Elder ṣe sọ, ọ̀dá owó awo olókun tún ṣe ìjàmbá fún àwọn tó lùgbàdí ọ̀ràn yìí láti tọju wọn.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button