Ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin tuntun ilẹ̀ Greenland péjọpọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọjó Ajé lẹ́yìn ìdìbò àpapọ̀ tó wáyé ni oṣù kẹta láìbìkítà ìhàlẹ̀ nígbà gbogbo ààrẹ Donald Trump láti darí ilẹ̀ ti kò ti gbòmìnira tán ti Erékùṣù Danish.
Jens-Frederik Nielsen, ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ti pè fún òṣèlú ìṣọ̀kan lẹ́yìn ìjàwé olùborí ẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ìdìbò osù kẹta, jẹ́ adarí ilẹ̀ Greenland ti ọjó orí rẹ̀ kere jùlọ nínú ìtàn yóò ní ìdojúkọ ìpènijà ààrẹ Trump.
Ọgbẹ́ni Nielsen sọ ní ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá pé ilẹ̀ Greenland yóò so yìgì mọ́ Ilẹ̀ Denmark tó pè ní ọ̀rẹ́ asúmọ́ni pẹ́kípẹ́kí jùlọ ti ilẹ̀ Greenland. O tun sọ pé, Ilẹ̀ Greenland fẹ́ ní òmìnira.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san