Àjọ IPCR Se Àtìlẹyìn Fún Ààrẹ Tinubu Látàrí Kíkéde Ìjọba Pàjáwìrì Ní Ìpínlẹ̀ Rivers
Àjọ tí ó wà fún àlàáfíà àti ìsàtúnṣe aáwọ̀, IPCR, ti lu Ààrẹ Tinubu lọ́gọ ẹnu látàrí kíkéde ìjọba pàjáwìrì ní Ìpínlẹ̀ Rivers, Orílẹ̀-èdè Naijiria
IPCR sàpèjúwe ìgbésẹ̀ Ààrẹ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́, tí ó sì dènà wàhálà, ìgbésẹ̀ náà yóò fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní ànfààní láti ronú pìwàdà, jókòó àlàáfíà láti fi òpin sí wàhálà tí ó ń wáyé
Alákòso àjọ náà, Ọ̀mọ̀wé Joseph Ochogwu sọ pé Ààrẹ gbé ìgbésẹ̀ náà lẹ́yìn ìfikùnlukùn àti ìwòye síwájú kí ìgbésẹ̀ ìkéde ìjọba pàjáwìrì tó wáyé.