Ìdókòwò Alábọ́dé Ni Ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ Ọrọ̀ Ajé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà – Mínísítà Jumokẹ Oduwọle
Mínísítà Fún Ilé Iṣẹ́, Òwò àti Ìdókòwò ti sàfirinlẹ̀ ipa tí ìsòwò alábọ́dé ńkó gẹ́gẹ́ bí ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ èyí tí ó ń mú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀ ajé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò ìdókòwò ti ọdún 2025, èyí tí ó wáyé ní Ọjọ́bọ̀ ní ìlú Makurdi. Ọ̀mọ̀wé Oduwọle sàlàyé ipa tí ìsòwò alábọ́dé ń kó nínú ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé, ó wá pàrọwà sí ọmọ Nàìjíríà láti farajì fún ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé
Ó tẹ̀síwájú pẹ̀lú títẹ́ pẹpẹ òfin àti àlàkalẹ̀ ìjọba èyí tí yóò mú ìlọsíwájú bá ìdókòwò alábọ́dé àti àwọn ètò tí yóò mú ìrọ̀rùn bá ìkópa nínú òwò síṣe