Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Panama Kọ Àbá Ìkìlọ̀ Wà Múni Ọlọ́pàá Arúfin Àgbáyé Fún Ààrẹ Tẹ́lẹ̀rí

320

 

Ọlọ́pàá Panma ti sọ pé àwọn ti kọ ìpè láti ọdọ ẹka àwọn amòfin láti wà mú ààrẹ àna, Ricardo Martinelli nípa ẹ̀sùn àtìpó tàbí o jẹ́ àtìpó olóṣèlú.

 

Martinelli jẹ́ ààrẹ tẹlẹ àárín gbùngbùn Amẹrika láti ọdún 2009 sì 2014, ti ó si ń gbé ní Ẹ́ḿbásì Nicaragua ní ìlú nlá Panama láti ìgbàtí ìjọba orílẹ̀-èdè náà ti gbìyànjú láti wá mú ti wọn fẹ́sùn kan pe ó ṣe owó ìlú kúmọkùmọ, ó kowo ìlú pàmò.

 

Ní ojó ojóbo, oṣiṣẹ àgbà kan ní ilẹ̀ Panama sọ pé ìjọba ti fi òǹtẹ̀ lùú pé Martinelli leè rin ìrìn-àjò bayii lọ sí Nicaragua, níbí tó ti fara soko tàbí fara pamọ́ sì fún ìgbà kan.

 

Wọ́n kó rí agbẹjọ́rò tàbí Ọlópàá arúfin àgbáyé kan fún Martinelli láti wà sọ tẹnu wọn. Agbẹnusọ fún Martinelli jẹ kó di mímọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára pé ẹ̀bẹ̀ tàbí ìpè láti wá múu ní wọn kò gbà wọlé.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button