Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti gúnlè ṣíṣe àmúlò anfààní ìmọ̀ ẹ̀rọ aláìlééfín láti ṣe ogbin Tòmátò lọ́pọ̀ yanturu pẹ̀lú Orílẹ̀ Èdè Netherlands.
Ẹni tíì ṣe Alákòóso àgbà ilé Àjọ Ìdàgbàsókè Òkòwò Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo State Agribusiness Development Agency, OYSADA) àti Oludamọran fún Gómìnà Seyi Makinde lórí Okòwò Iṣẹ́ Àgbẹ̀, Debo Akande ló sọ ọ̀rọ̀ yii lásìkò tí aṣojú Ilẹ̀ Netherlands sí Orilẹ Èdè Nàìjíríà, Michael Deelen ṣe àbẹwò sí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Akande sọ di mímọ̀ pé, Gómìnà ti pàṣẹ fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn láti bẹ̀rẹ̀ ọgbin Tomato pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ aláìlééfín (Greenhouse technology) lójúnà àti ṣe ìkúnlápá fún àwọn àgbẹ̀ olókó àrojẹ.
Alákòóso OYSADA, ẹni tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àbẹ̀wò àwọn aṣojú ilẹ̀ Netherlands yóò fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ànfààní láti ṣe ọgbin Tòmátò lọ́pọ̀ yanturu ní àfikún pẹ̀lú bi Gómìnà ṣe ṣe ìpàdé pẹ̀lú Àjọ Olókoòwò ilẹ̀ Áfíríkà (Africana Business Forum) ni Orilẹ Èdè Ethiopia nínú èyí ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni àfojúsùn láti máa ṣe ọgbin Ẹ̀wà Soya (Soya beans).
Akande wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò yẹ kí irú ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 nínú èyí tí iye owó Tomato ga tó bẹẹ tí kò ṣeé rà fún ara ìlú tó wà ni ìsàlẹ̀ Ọya. O wá ṣàlàyé pe o yẹ ki Tomato máa wá lọpọ yanturu ni gbogbo àsìkò ni iye owó tí kò gara.
Akande tun sọ síwájú pe, àwọn Orilẹ Èdè bíi Isreali àti Dutch ló ní ìmọ̀ nípa ọgbin Tòmátò lágbayé, tó sì jẹ́ pé Ilẹ̀ Netherlands náà ti darapọ̀ mọ́ Orílẹ̀-èdè to n ṣe ogbin Tòmátò lọ́pọ̀ yanturu. O wá fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà ti ṣetán láti kọ bi wọn ṣe n se ogbin Tòmátò pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ aláìlééfín.
Alákòóso OYSADA ṣàlàyé pé, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti se àgbéyẹ̀wò ìmọ̀ ẹ̀rọ aláìlééfín yìí ni Oko Fáṣọlá nibi ti wọn ti rí bí ìmọ̀ ẹ̀rọ náà ṣe n ṣiṣẹ, tó sì jẹri síi pé ilé iṣẹ náà ti n pèsè Tomato pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ aláìlééfín yìí tí wọn sì ti n tá Tomato jákèjádò awọn ọjà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Ṣáájú nígbà to n sọ̀rọ̀, Aṣojú ilẹ̀ Netherlands, Michael Deelen jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn tó ṣe àbẹ̀wò sí Gómìnà Makinde wá láti ṣe okòwò àti láti wo ipa ti ìjọba lè ko nínú ìdókòwò pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Deelen fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ilẹ̀ oko láti ṣe ọgbin Tomato ju Ìpínlẹ̀ yòókù to wa ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà lọ.
Bákan náà ni Olugbani nímọ̀ràn ni Ofiisi Aṣojú, Inge Tenniglo, ṣàlàyé pé Ìjọba Dutch ṣetan láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lójúnà àti mú kí ìpèsè Tomato gbéra.

Bákan náà ni Aláàmójútó Àgbà lórí ọ̀rọ̀ tó níí ṣe pẹ̀lú Ilẹ òkèèrè àti Okòwò (International and Economic Affairs), Ima Meijer sọ di mímọ̀ pé Ìjọba Dutch ni ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè oúnjẹ ọlọ́jọ́ pípẹ́ ti wọn sì ní ìgbàgbọ́ pé ìmọ̀ ẹ̀rọ aláìlééfín jẹ ọ̀nà kan gbòógì láti ṣe èyí.
Abiola Olowe
Ìbàdàn.