Ẹ Fi Àdúrà Jagun Fún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Lásìkò Ààwẹ̀ Ramadani- Adarí Ilé Asòfin Ati Igbákejì Rẹ̀ Pàrọwà Sí Àwọn Mùsùlùmí
Adarí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin, Ọ̀gbẹ́ni Abbas Tajudeen ti pàrọwà sí àwọn Mùsùlùmí ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbàdúrà fún Orílẹ̀-èdè àti àwọn adarí, bí ààwẹ̀ Ramadani se gbérasọ
Abbas sàfirinlẹ̀ pàtàkì ìsọ̀kan Orílẹ̀-èdè léyìí tí ó se pàtàkì fún elésìn gbogbo láti tẹramọ́ àdúrà ní gbogbo ìgbà fún àseyọrí àwọn tí ó di ipò òsèlú mú, àwọn Ọba alayé àti adarí ìjọ Ọlọ́run ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan
Ó pè fún àdúra àtìlẹyìn fún Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin ẹlẹ́kẹ̀ẹwàá àti ìgbìmọ̀ ìsàkóso ìjọba àpapọ̀ fún àseyorí aláìlẹ́gbẹ́ àti ìdàgbàsókè tí ó múná dóko. Ó wá gbàdúrà kí ẹ̀mí rẹ́yìn osù àti àsepé iṣẹ́ nínú osù abiyì náà