Ìjọba Àpapọ̀ Pẹ̀lú Àjọṣepọ̀ Banki Àgbáyé Ṣe Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Fún Ọ̀ọ́dúnrún Olùkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ọwọ́ Ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà
Kò dín ní Ọ̀ọ̀dúnrún (300) olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìkọ́ṣẹ́ ọwọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà tó ṣe alabapin nínú Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọsẹ̀ mẹta ti ilé iṣẹ Ìjọba Àpapọ̀ to n rí sì ètò ẹ̀kọ́ se agbatẹru rẹ̀ pẹ̀lú ibaṣepọ Bánkì Àgbáyé.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà eléyìí tó níí ṣe pẹ̀lú bi a se lè fi ìmọ̀ ṣe agbekalẹ èròngbà ẹni ṣe iṣẹ ọwọ́ (Innovation Development and Effectiveness in the Acquisition of Skills, IDEAS) ti wọn mú wá sí ìparí ni ọjọ́ Kọkanlelogun oṣù Kejì ọdún yìí (21/02/2025) lo pin sí ìpele mẹta nínú eyi ti ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ (Pedagogy) eléyìí to túmọ sí ẹ̀kọ́ nípa onírúurú ọ̀nà tí olùkó le gbà láti fi òye yé awọn akẹ́kọ̀ọ́; nígbà tí ìpele kejì jẹ́ níní òye lílò ìmọ̀ ẹ̀rọ ayélujára (Digital Literacy); ti ìpele kẹta sì dà lórí ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ olukulùku (Specific Trade Training).
Nígbà ti Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ ni Orilẹ Èdè Nàìjíríà, ti Ọ̀mọ̀wé Muibat Olodo tíì ṣe Alàkóso Ìmọ̀ Ẹrọ àti Ìmọ̀ Sáyẹnsì sójú rẹ̀ níbi ètò náà jẹ́ kó di mímọ̀ pé, nínú ètò ọrọ̀ ajé eléyìí to n fi ojoojumọ yípadà, níní ìmọ̀ àti didàgbàsókè nípa ìmọ̀ ìkọ́ṣẹ́ ọwọ jẹ́ ọpa kutele fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé.
Bákan náà ni Ọ̀mọ̀wé Olodo ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ to n ri sì ètò ẹ̀kọ́ ti pinnu láti pèsè ètò ẹ̀kọ́ tó yè kooro eléyìí ti yóò bá ìgbà ode òní mu.
O wa rọ gbogbo àwọn tó kópa nínú Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà láti ṣe àmúlò ìmọ̀ ti wọn ti kọ lójúnà àti mú ayípadà ọtun dé bá àwọn akékòó wọn.
Alága ètò náà, Ọ̀mọ̀wé Tony Okwa fi dá wọn lójú pé ìdánilékòó yii yóò mu ki àwọn ènìyàn rí dájú pé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ iṣẹ ọwọ́ ni anfààní to pọ, ni pataki jùlọ ní orílé èdè Nàìjíríà to jẹ ọkan lára àwọn orilẹ èdè ti ṣẹṣẹ n dìde.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Komisana fún ètò ẹ̀kọ́ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Amofin Abiodun Abdul-Rahman fi dá àwọn tó ṣe agbatẹru ètò náà àti àwọn olukopa lójú pé digbi ni Ijọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wà lẹ́yìn wọn.
O wá fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ti Orile ede Naijiria yóò bá fẹ yípadà láti máa sinmi le epo bentiro, o ni láti mú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ iṣẹ ọwọ́ lọ́kúnkúndùn.
Komisana wa sọ síwájú pe, àsìkò ti tó báyìí láti mú ayípadà dé bá ọrọ̀ ajé Orilẹ èdè Nàìjíríà.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ, Ọgá pátápátá ilé ẹkọ Gbogboniṣe Ìbàdàn (The Polytechnic, Ìbàdàn), Ọ̀mọ̀wé Taiwo Lasisi, ti Adari ẹka Káràkátà àti Ìṣòro-n-gbesi (Faculty of Business and Communication Studies) ni ile ẹkọ náà, Ọ̀mọ̀wé Kehinde Faniyi gba àwọn olukopa náà níyànjú láti lò ìmọ ti won ti kọ fún ìlọsíwájú àti láti kojú ìpèníjà ode òní.
Bákan náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyetunde Adeaga to ṣe akojọpọ ètò IDEAS ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà tún gba àwọn olukopa níyànjú láti ṣe àmúlò ìmọ̀ ti wọn ti gba, to sí lu awọn oludanilekọọ lọ́gọ ẹnu fún iṣẹ́ ribiribi ti wọn ti ṣe láti bíi ọsẹ mẹta ṣẹ́yìn.

Nígbà ti wọn n fi èròngbà wọn nípa ètò náà hàn, ọgbẹni Owolabi Olufemi tó jẹ́ olùkọ ilé ẹ̀kọ́ Government Technical College, Oke-Igbo ni Ìpínlẹ̀ Ondo àti Abílékọ Iyiade Afolake láti ile ẹ̀kọ́ Government Technical College, Ikorodu ni Ìpínlẹ̀ Èkó gbe osuba kare fún Ìjọba Àpapọ̀ fún àgbékalẹ̀ yìí, ti wọn sì pe fún irufẹ ètò báyìí lójó iwájú.
Abiola Olowe
Ìbàdàn