Àwọn olókìkí ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ṣètọrẹ sí ilè ìkàwé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Ibrahim Badamosi Babangida, láti wà ní Minna, Ìpínlẹ̀ Niger.
Ọjọ́bọ̀ ní wọ́n ṣé ìfilọ́lẹ̀ ìwé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà, ìtàn-àkọọlẹ tí Ààrẹ ológun tí wọ́n pé àkọlé rẹ̀ ní; Ìrìn-àjò kán nínú Iṣẹ́, onígbá méjì, èyí tí yóò ṣé ikowojọ fún Iṣẹ́ Ilè-ìkàwé Ààrẹ náà.
![]()
Àwọn ènìyàn jankan jankan àti àwọn olókìkí ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló ṣe agbatẹru àtìlẹ́yìn ẹbùn owó ìyìn náà.
Alága àti Olùdásílẹ̀ BUA, Abdul Samad Rabiu, ló bẹ̀rẹ pẹ̀lú owó ẹbùn bílíọ̀nù márùn Náírà (₦5b), bí Gen. Theophilus Danjuma náà ṣé fí bílíọ̀nù mẹta náírà (₦3b) kún ẹbùn owó náà.
Ọkùnrin ọlọlá jùlọ ní Áfíríkà, Aliko Dangote, ṣé ìlérí bílíọ̀nù mẹjọ Náírà (N8b) láàrín ọdún mẹrin tó mbọ̀.
Àwọn owó ẹbùn pàtàkì mìíràn láti ọ̀dọ̀ Sẹnetọ̀ Sani Musa àádọtalélugba mílíọ̀nù Náírà (N250m) àti Mustapha Chike-Obi ṣé inawọsi méjì pèlú àádọ́ta mílíọ̀nù Náírà (N50m) láti ọ̀dọ̀ Bánkì ‘Fidelity’ àti ọgọrùn mílíọ̀nù mìíràn (N100m) láti ọwọ tirẹ̀.

Ààrẹ Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio, náà ṣèlérí àádọ́ta mílíọ̀nù Náírà (N50m), nígbà tí Ìgbákejì rẹ̀, Barau Jibrin, ṣèlérí ogún mílíọ̀nù Náírà (N20m)
Sẹnetọ̀ Aliyu Wadada, tó sójú fún Ààrẹ Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà náà, Alagba Godswill Akpabio àti Jibrin, ṣé àdéhùn mílíọ̀nù mẹ́wàá Náírà (N10m).
Comments are closed.