Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti buwọ́lu ìyànsípò Ọ̀mọ̀wé Vincent Isegbe fún ìgbàkejì gẹ́gẹ́ bí alákòóso àgbà fún ẹka tí ó ń darí ètò ọ̀gbìn ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Nínú ọ̀rọ̀ tí agbẹnusọ ààrẹ, Ajuri Ngalale fi ọwọ́ sí, ó sọ wípé Ọ̀mọ̀wé Isegbe yóò se àkóso ẹka náà fún ọdún márùn-ún míràn
Ngalale sọ pé, ààrẹ gba adarí tuntun náà níyàjú láti tẹ̀síwájú nínú ojúse rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó se wà lára àwọn mẹ́ta nínú ẹka ìjọba àpapọ̀ tí ó peregedé jùlọ