Ikọ̀ ọmọ ogun Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sekúpa àwọn alákatakítí ikọ̀ Boko Haram ni àgbègbè Igabi, Giwa ní ìjọba ìbílẹ̀ Brinin Gwari, ìpínlẹ̀ Kaduna
Olùfọ̀rọ̀léde fún àjọ ọmọ ogun, ọ̀gágun Onyema nwachukwu ni ó fi ọ̀rọ̀ náà lédè ní Ọjọ́bọ̀, ó sàlàyé pé àjọ ọmọ ogun ń là kààkà láti palẹ̀ àwọn agbésùmọ̀mí náà mọ́ láti fún àwọn ènìyàn ìlú ní àlàáfíà
Ìròyìn fi yéwa pé olórí àwọn alákatakítí náà, Boderi, ẹni tí ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìkọlù tí ó ti wáyé ni ó pàdánù ẹ̀mi rẹ àti ojúgbà rẹ̀ Badejo.