Látàrí àsekágbá eré ìdárayá AFCON tí ìrètí wà pé yóò wáyé ní ọjọ́ Àìkú níbi tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles ti Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò ti figa -gbága pẹ̀lú ojúgbà rẹ̀, Elephant ti Orílẹ̀-èdè Ivory Coast, ẹka ìfọ̀rọ̀léde Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti pè fún àtìlẹyìn àwọn ọmọ Nàìjíríà
Mínísítà fún ìfọ̀rọ̀léde, Mohammed Idris se ìfiléde wípé ẹka ìlanilọ́yẹ̀ yóò pín àsìá pélébé-pélébé fún ọmọ Nàìjíríà fún ìsàfihàn àtìlẹyìn wọn
Idris wá rọ àwọn ọmọ Naijiria ti o wa ni Orilẹ-ede Ivory Coast lati tú yááyá lọ sí pápá eré ìdárayá, láti se kóríyá fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles