Ààrẹ Namibia, Hage Geingob, kú ní ẹní ọdún méjìlèlọgọ́rin (82) níbí tó tí ń gbá ìtọjú ní Ilè-ìwòsàn kàn ní Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè náà, Windhoek.
Ìgbákejì Ààrẹ Namibia Nangolo Mbumba ló kéde ikú Ọ̀gbẹ́ni Geingob ní kùtùkùtù ọjọ́ Àìkú, tí ìyàwó àtí àwọn ọmọ rẹ̀ ń bẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Geingob náà ní àyẹwò sọ́ pé Ó ní ààrùn jẹjẹrẹ èyí tó sọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní Oṣù tó kọjá.
Ìbó gbogbogbòò Orílẹ̀-èdè Nàmíbíà ní yóò wáyé nínú Oṣù Kọkànlá ọdún yìí.
Ẹ̀gbẹ́ òṣèlú Swapo tó tí ń ṣàkóso Orílẹ̀-èdè náà látí ìgbà òmìnira wọ́n ní ọdún 1990, ti yan Arábìnrin Nandi-Ndaitwah gẹ́gẹ́ bí Oludije ipò Ààrẹ labẹ́ àsìá wọ́n.
Arábìnrin Nandi-Ndaitwah náà ní igbakeji Alákóso Àgbà tí Orílẹ̀-èdè Namibia, àti pé yóò dì Ààrẹ Obìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè náà tó bá bóri.