Amú-bọ́ọ̀lù fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles, Stanley Nwabali ni kò ì tí ì sí àrídájú pé yóò kópa nínú ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ tí yóò wáyé láàrin ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Angola ní ọjọ́ Ẹtì tí ó ń bọ̀, ní pápá eré ìdárayá Houphouet Boigny, Abidjan látàrí bí ó se fi arapa nínú ìkópa tí ó kọjá
Ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náà fi arapa níbi ìfagagbága tí Super Eagles ti fi àgbà han ojúgbà rẹ̀ ti Orílẹ̀-èdè Cameroon pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo
Francis Uzoho ni ó rọ́pò rẹ̀ láti parí eré ìdárayá náà, tí kò sì tí ì sí àrídájú pé ó ti ní àlàáfíà tí ó péye láti tẹ̀síwájú