Ikọ̀ Morocco fi ata sí ojú ikọ̀ Zambia pẹlú ayo kan dondo sí òdo (1-0) ni ọjọ Ojoru ni ibi idije Africa Cup of Nations (AFCON) to n lọ lọwọ ti won sì lọ sókè tente tabili ni isori F, èyí rán ikọ̀
Ivory Coast lati pada sinu ìdíje náà.

Ikọ̀ Morocco ni àmì ayò meje ṣaaju ikọ̀ Democratic Republic of Congo tó ta ọ̀mì odò odo (0-0) pẹlu Tanzania .
Iko Zambia parí sí ipò kẹta pẹlu àmì ayo meji ti ko sí to lati jade laarin awọn mẹrin tó se daradara julọ laarin ikọ̀ mẹta to gbiyanju jùlọ.
Ikọ̀ Ivory Coast gba ìlù gba ijo láti se atilẹyin fún ikó Morocco ni pápá isere Laurent Pokou
nitori wọn mọ pé ti ikọ̀ Zambia ba ti subu, awọn yóò yege sí ìpele ẹlẹ́nimẹ̀ríndínlógún.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san