Gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi, Olóyè Francis Nwifuru ti yan alága tẹ́lẹ̀rí fún ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn ìpínlẹ̀ Ebonyi, Anthony Nwizi gẹ́gẹ́ bí adarí tuntun fún ilé iṣẹ́ ìfọ̀rọ̀léde ìpínlẹ̀ náà
Síwájú ìyànsípò Nwizi, ó jẹ́ olùbádámọ̀ràn àgbà sí Gómìnà lórí ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀ àti ètò ẹ̀rọ ayélujára
Ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà se sọ wáyé láti rí i dájú pé ìdàgbàsókè bá ilé iṣẹ́ ìfọ̀rọ̀léde ìpínlẹ̀ náà nítorí ìrírí rẹ àti ọlọ́pọlọ pípé tí Nwizi jẹ́.