Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbáyégbádùn Àwọn Dókítà Onímọ̀ Ìsègùn Òyìnbó Se Pàtàkì- Ẹgbẹ́ Àjọ Náà Tẹ́ Pẹpẹ ọ̀rọ̀

279

Ẹgbẹ́ Àwọn Dókítà Onímọ̀ Ìsègùn Òyìnbó ẹka ti ìpínlẹ̀ Ogun ti fi ẹ̀dùn ọkàn hàn látàrí ìgbé ayé ìlekoko tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà ń gbé pẹ̀lú iṣẹ́ àsekúdórógbó látàrí iná mọ̀nà-mọ́ná tí ń se mọ́na-mọ̀na ní gbogbo ìgbà.

 

Alága Àjọ náà, Dókítà Azim Ashimi sọ pé àwọn ohun èlò ní àwọn ilé ìwòsàn gbogbo ni kò tó rárá èyí tí ó ń mú àwọn dókítà siṣẹ́ ju bí ó ti se yẹ lọ

 

Ashimi fi ọ̀rọ̀ náà léde fún àwọn akọ̀ròyìn níbi tí ó ti pàrọwà sí ìjọba àpapọ̀, ìpínlẹ̀ láti gba àwọn Dokita akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ síṣẹ́, kí wọ́n sì pèsè àwọn ohun èlò àmúsiṣẹ́ tí ó péye fún ìdàgbàsókè àwùjọ

 

 

 

Comments are closed.

button